
Sexual Health
Female (left) and male (right) reproductive systems (Medscape)
Ikora Eni N'ijanu:
Eyi tun mo si wipe ki yoo si ibalopo bi ifenu-konu, ifowokan oju ara ako tabi abo rara ati
Ibasepo Nitooto, Eyi Olojo Gbooro
Eyi tun mo si wipe ki yoo si ibalopo pelu elomiran ayafi ako kan ati abo kan.
Roba idaabobo
Lilo roba idaabobo je ona kan gboogi ti a fi lee d’ena arun kogboogun ati oyun aito.
AKIYESI: O seese ki eniyan ni arun kogboogun ti oju ara ba kan ara won laini ibalopo tabi nipa fifi enu si oju ara eniyan. Ko gbodo si ibalopo ti eniyan ba ni arun kogboogun naa.
ARUN IBALOPO: HERPES, CHLAMYDIA, GONORRHEA, SYPHILIS
Awon arun wonyi ni eniyan lee ni nipa ibalopo lati oju ara, iho idi, fifi owo kan oju ara ati beebee lo. Awon arun wonyi lee ba ago ara wa Gje, won si lee pani. A o maa tele awon isise lati fun wa ni oye awon aisan wonyi gege bi a ti se alaye re siwaju ati siwaju sii.
Kinni ohun ti n fa Herpes? Eleyi je kokoro ti o n fa irora, egbo adaajinna, ati ailera. Ibalopo alaini aabo a maa fa aisan gege bi a se mon. Idaniloju ni wipe enikeni ti o ba n ni ibalopo liaise ayewo, iru eni bee lee ni arun kogboogun ti a mo si HIV/AIDS. Bakana, arun atosi je nkan ti eniyan lee kan lati ara enikeni ti o ba ni aisan naa. Fifi enu si oju ara eniyan yala ako tabi abo je nkan ti o lewu pupo.
O se pataki ki a fi to gbogbo eniyan wipe arun HIV/AIDS yii ko gboogun. Nitori idi eyi, lati d’ena aisan ati awon arun kogboogun, o se pataki fun eniyan lati mu ara duro tabi lo roba idaabobo eyi ti a mon si Condoms.
ISE: Awon arun ibalopo yi jo ‘ra won lopolopo. Arun kogboogun HIV a maa je o le koko lati maa ba aisan ara eniyan ja. Irufe eni ti o ba ni arun kogboogun a maa se aisan kekeeke. Bi eniyan ba ti n se aisan die-die, o se pataki ki iru eni bee tete lo se ayewo ni ile iwosan ijoba tabi ti aladani. Arun kogboogun a maa gbe inu eje, omi ara, omi oya. Arun kogboogun HIV kii si ninu oogun ara, irun tabi eekana. A ko lee ni arun kogboogun nipa jije ounje pelu eniti o ni arun naa ayafi ti eni naa ba ni egbo ni enu. A lee ko arun kogboogun HIV nipase abefele, tatoo, obe, tabi nipase idabe.
Titi di asiko yi, ko ti si ogun itoju fun arun kogboogun HIV. Enikeni ti I ba ni aisan naa yoo maa lo oogun titi di ojo aye re. Awon olubanisoro l’ori oro arun kogboogun HIV gbodo wa ni gbogbo awon ile iwosan kaakakiri. Awon alarun HIV tun le lo si JEI paralegal.
Awon irisiri. E je ki a gbe yewo bi o ba lee dahun awon ibeere wonyi:
- Nje eniyan lee ni arun kogboogun nipase efon? Beeni abi beeko
- Nje eniyan lee ni arun kogboogun nipase ibalopo pelu orisirisi awon
eniyan? Beeni abi beeko
- Eni ti o ni arun kogboogun gbodo maa l’oogun ni ojojumo? Beeni abi beeko
- Eniyan lee ni arun kogboogun nipase lilo abere/okinni? Beeni abi beeko
- Pelu itoju ti o mu’na d'oko ,nje eni ti o ni arun kogboogun lee gbe igbe aye alafia bi? Beeni abi beeko?
- Bi obi ba ni arun kogboogun, nje omo naa lee nibi? Beene abi beeko?
- Eniyan lee ni arun kogboogun nipa jije ounje ti eni to ni arun naa pese? Beeni abi beeko?
IJIRORO: Nje awon ona miran wa ti eniyan lee gba lati ni arun kogboogun HIV? Awon ona wo ni? Fun idahun si awon ibeere wonyi, e je ki a wo oju ewe 29 Iwee Pathfinder International Handbook. Idi ti awon wonyi sele se ibapade arun kogboogun HIV.
IDARAYA: E pin ara yin, ki egbe kookan se ipese orin bi eniyan se lee ni, se itoju ati d’ena arun kogboogun HIV. Ki egbe kookan tun wa parapo lati k’opa ninu idanwo.
Sise Ayewo: Orisi ayewo meji l’owa: Ayewo oni kia-kia, eyi ti eniyan a maa lo abere kekere nninu ago ara eniyan lati lee s’ayewo eje. Nipase eleyi, esi ayewo naa yoo jade laarin wakati Kan gboogi.
Getting Tested: There are two kinds of tests. Rapid Test - Using a small pin, a drop of Bi eniyan ba ni arun kogboogun HIV, o se pataki lati lo se ayewo eje miran ni ile iwosan. Eleyi. Esi ayewo naa yoo jade leyin ojo meji. Ki eniyan meji jowo ara won lati se nkan wonyi:
1) E ti gbo itan omo obinrin wundia ti o ni arun kogboogun HIV nipase eso jije I eyi ti o towo eni ti o n ta eso wa. Se alaye fun iya omo obinrin naa.
2) O ko eko ni yara ikawe wipe if’enu k’onu a maa fa aisan HIV ati loli ilarun pelu eni ti o ni arun naa ba Bawo ni iwo yoo se dahun si iru oro yii?
3) Awon alajogbepo ni adugbo re n d’eye si eni o ni arun kogboogun. Won ko fe ba eni naa se papo. Bawo ni o se lee bawon s’oro lati mase b’eru?
IF’ETO S’OMO BIBI:
Kini idi ti awon eniyan se n se if’eto s’omo bibi?
Wo iwe owo re: if’eto s’omo bibi oju ewe kinni si ikerin. Gege bi egbe, ka awon ohun ti eniyan lee se lati se eto if’eto s’omo bibi lati oju ewe 5. Ni apa isale, omo’binrin ati Olori Esin kan wa. S’alaye ohun ti esin so nipa if’eto s’omo bibi. Bawo ni awon onise ilera se n se ojuse nipa if’eto s’omo bibi? Kini ojuse re gege bii CHE ti q ba n s’oro nipa if’eto s’omo bibi?
ILA’NA IF’ETO S’OMO BIBI: Pin si otooto ki o si dahun awon ibeere ti o tele:
1) Bawo ni awon sele d’ena arun ibalopo? ________________________________________________________________________________
2) Awon ilana wo ni o f’aye ako ati abo lati se if’eto s’omo bibi? ________________________________________________________________________________________________________________________________________________________________________________________________________________________________________________
3) Ilana wo ni o rogbokun le obinrin? ________________________________________________________________________________________________________________________________________________________________________________________________________________________________________________
4) Ilana wo ni o rogbokun okunrin?________________________________________________________________________________________________________________________________________________________________________________________________________________________________________________
5) Ilana wo ni o wopo ni orile ede Nigeria? ________________________________________________________________________________________________________________________________________________________________________________________________________________________________________________
6) Nje irufe naa wa ti o ko ti ri tabi gbo ni orile ede Nigeria? ________________________________________________________________________________________________________________________________________________________________________________________________________________________________________________
7) Wo oju ewe 7. Awon anfani ati ewu wo l’owa ninu ilana naa?
________________________________________________________________________________________________________________________________________________________________________________________________________________________________________________
Fun ise amunrele, lo se Ilana kinni daradara. Ri daju wipe o lo iwe ti a fi nko ni ki o si pada wa lati wa koni ni yara ikeko.
IJIRORO: Lati ibere eko ni a ti s’oro nipa CHEs. Okan l’ara awon ofin naa ni asiri. Eleyi lee je oyun sise. Oyun sise je okan ninu awon idi ti obinrin fi n ku ni orile ede Nigeria. Kini ohun naa ti iwo yoo se ti omo obinrin ba wa si odo re ninu agbara eje nipase oyun sise?
IDARAYA: Pin yara na si meji. Oluko yoo kaa awon oro tabi ibeere naa jade. Eyikeyi ninu egbe ti o ba dahun ibeere naa ni a j’awe olubori.
ROBA IDAABOBO: Lilo roba idaabobo je ona kan lati d’ena arun ibalopo ati oyun aito. A gbodo maa loo gege bi oti to ati bi o ti ye ni igba kuugba lati d’ena arun kogboogun. Bakana, kii se eewo fun oko ati iyawo lati lo roba idaabobo lati d’ena oyun aito. E maa lo awon idi agbon oloorun didun tabi omi ki e si ri daju wipe e ko lo roba idaabobo eyokan ni emeji.
Ki e gbiyanju lati maa ni roba idaabobo ninu ile n’igba gbogbo .E ko gbodo lo roba idaabobo atijo. E gbinyanju lati ye eyin paali roba idaabobo naa wo lati ri daju wipe kii se ayederu. E mase fi roba idaabobo s’inu apo eyin. E mase fi eyin ja roba idaabobo
ISE SISE: E pin si ona meji. E pada lo si Pathfinder International Handout ki e si oju ewe 32. Ka awon ofin naa ni sise n tele. Ki e lo roba ati igo ti a fun yin lati se nkan naa. Ranti lati se e pelu suuru. Eniyan meji li o gbodo se ise sise naa.
ISE: Ka oju ewe 43 – 35. Se ilana bi a ti n lo roba idaabobo ti obinrin. Ranti lati se pelu suuru.
ISE GBOGBO GBO OYUN NINI
Orisirisi awon irora ni ara obinrin maa n la koja l’asiko il’oyun. Gbogbo eya ara obinrin a maa kuro ni ipo ti o wa lati fi aaye gba oyun naa lati d’agba .Fifun omo l’oyan je ona kan gboogi ti a fi lee mo wipe omo ti di bibi. Lehin ti a ba bi omo, a maa gba akoko die ki ara obinrin to bosi ipo ti o wa tele.
NINI OYUN: Obinrin lee ni oyun bi iru obinrin naa ba ti n se nkan osu ti di igba ti nkan osu naa yoo duro. Oyun a maa w’aye n’igba ti obinrin ba n mura lati se nkan osu eyi ti awon nkan funfun bi eyin n jade ninu oju ara obinrin naa, ti ato omo kunrin naa si wo inu oju ara obinrin naa. Eleyi ko tun mo si wipe oyun tun lee w’aye. Ni iwon ‘gba ti eyin bati d’agba, awon eroja yoo sopo. Ato okunrin lee wa ninu obinrin fun ojo marun laiti ti se nkan osu.
Awon eniyan kan le ma ni omi nipase ailee b’imo. Awon aisan naa lee d’ena il’oyun obinrin bii aaisan tabi arun r’omo l’apa r’omo l’ese. Awon orisirisi nkan lo lee fa ail’oyun obinrin bii: ailera, jije eran ju, arun r’omo l’apa r’omo l’ese, arun inu eje, ati beebee lo. Ayika ti o doti tun lee fa air’omo bi obinrin. Ato okunrin ti o ba kere ju bi o ti yelo naa lee fa ail’oyun obinrin.
O se pataki ki a lo si ile iwosan fun itoju ati idani l’eko.
IJIRORO: Taani eni idal’ebi l’asiko ail’oyun ? Nje awon eniyan a maa lo ri Dokita l’ori ati l’oyun ati ibi’mo ?Bawo ni o se lee se iranlowo gege bii CHE?
IPELE IL’OYUN ATI AMOJUTO AWON OBI
Bi obinrin ba ti ni oyun, irufe obinrin naa gbodo maa se ayewo loore koore. O gbodo maa je awon ounje ti ohun s’ara loore. Ogbodo maa lo si ile iwosan deede lati gba idanileko.
1 s t T r i m e s t e r ( Osu 1 - 3 ) Se ipinnu l’ori TBA tabi Ajo Eleto Ilera. Se ayewo l’ori arun ibalopo ati awon aisan miran. Bi oloyun ba ni arun kogboogun, o se pataki ki o loo oogun lati d’ena aisan naa lati maa lee ran omo inu re.
Obinrin lee ni isoro omo bibi ti irufe obinrin naa ko ba se ohun ti o to ati ohun ti o ye. A ko gbodo fo aye gba aboyun lati maa se ise ti o l’agbara ju. Bakana, alaboyun gbodo maa maa se je awon ounje ti o s’ara ni anfani.
2 n d T r i m e s t e r ( Osu 4 - 6 ) Alaboyun gbodo maa lo awon oogun asara loore ni awon akoko yii. Eleyi yoo d’ena aisan tabi arun lati w’onu ara alaboyun naa.
3 r d T r i m e s t e r ( Osu 7 - 9 ) Ni asiko yii, o se pataki ki Dokita s’ayewo l’ara alaboyun naa lati rii daju wipe omo inu naa wa ni ipo ti o dara. Ti omo ko ba wa nipo to dara, alaboyun naa lee ku n’igba ti o ba n robI. Leyin omo bibi, o se pataki lati ri daju wipe olubi omo wa ni ita. Ti olubi omo ko ba si ni ita, iya omo naa lee ku.
Omo bibi ko gbodo koja Wakati Meji. Ti o ba ju beyen lo, iya ati omo naa lee ku. Leyin omo bibi, eniyan tun gbodo se ayewo ni ile iwosan lati rii daju wipe ilera pipe wa l’ara iya omo naa.






Ibalopo Alail’Ewu


